Poem on Thanksgiving for Promotions

Elédùmarè Ministry

Verse

Ìbà!
Ìbà ni fún Olúwa Ẹlẹ́dàá wa! 
Ẹni tí ó ti mọ̀ gbogbo ìgbà àti àkókò. 
A fi ọpẹ́ fún Olúwa wa, 
Ẹni tí n’gbéniga nígbà tí a kò rò.

Chorus

Ìgbéga kò wá láti ìwọ-oòrùn, 
Ìgbésókè kò wá láti àríwá. 
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé, 
Láti ìtẹ́ Elédùmarè ni gbogbo wọ́n ti wá. 

Verse

Elédùmarè tí ó gba ń sọ ẹrú di ọba. 
Ẹni tí ó ń gbé orí ìwẹ̀fà sókè. 
Ẹni tí ó n yí ìgbà àti àkókò pada. 
Ìbà fún Elédùmarè. 

Verse

Ìbà ló yẹ kí á ṣe fún Elédùmarè.
Ẹni tí ó dáríi gbogbo ìgbésẹ̀ wa jì wá. 
Tí ó ń mú wa gòkè àgbà l’ójojúmọ́ . 
Ìyìn fún Elédùmarè. 

Verse

In another time’s forgotten space
Your eyes looked through your mother’s face
Wildflower seed on the sand and stone
May the four winds blow you safely home

Verse

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Elédùmarè Ọba ògo. 
Ẹnití ó n gbé ní dídè láti ipò ìrẹ̀lẹ̀. 
Aláṣẹ gíga-gíga ayérayé. 
Ìbà Rẹ ooo, ìbà. 

Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè 
Ìbà fún Elédùmarè 
Ìbà Àṣẹ

Leave A Comment

Shopping Cart (0 items)

Subscribe to our newsletter

Sign up to receive latest news, updates, promotions, and special offers delivered directly to your inbox.
No, thanks