Poem For Mothers
Bíi ọmọ-ìkókó tí kò rí ẹnì tọ́ òun,
Bẹ́ẹ̀ ni ilé ayé rí kí Elédùmarè tó dé.
Ilé ayé jókòó ní júujùu,
Àní nínú agbalagbúlù omi ẹkún.
Chorus:
Abiyamọ ayérayé ni Ẹlẹ́dàá wa.
Ẹnití Ó n tọ́ ọmọ-ọmú pẹ̀lú ìyáa rẹ̀.
Ó ń pèsè fún gbogbo ohun ẹlẹ́mìí.
Gbogbo wọn pátá ni Ó ń ràdọ̀bò.
Ṣùgbọ́n láìpẹ̀ ìyá ayé dé!
Elédùmarè gbé ayé lẹ́yìn bíi ọmọ-ìkókó.
Ó fi ọjà ìrọra àti ìkẹ́ wée.
Ó sì tún fi èémí ìyè tọ́ọ.
Chorus:
Abiyamọ ayérayé ni Ẹlẹ́dàá wa.
Ẹnití Ó n tọ́ ọmọ-ọmú pẹ̀lú ìyáa rẹ̀.
Ó ń pèsè fún gbogbo ohun ẹlẹ́mìí.
Gbogbo wọn pátá ni Ó ń ràdọ̀bò.
Báyìí gẹ́gẹ́ ni màmá tó bí mi ṣe.
Ó wẹ̀ mi kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ìrọbí.
Ọmú ìyè ni mo mú láyà rẹ̀.
Ìkẹ́ àti ìgẹ̀ ló fi tẹ́milọ́rùn.
Chorus:
Abiyamọ ayérayé ni Ẹlẹ́dàá wa.
Ẹnití Ó n tọ́ ọmọ-ọmú pẹ̀lú ìyáa rẹ̀.
Ó ń pèsè fún gbogbo ohun ẹlẹ́mìí.
Gbogbo wọn pátá ni Ó ń ràdọ̀bò.
Màmá mi tọ́ mi bí Ẹlẹ́dàá ti tọ́ ilé-ayé.
A bá mi wí bí mo bá ṣẹ̀.
A mú mi lórí wù bí mo mú inú rẹ̀ dùn.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ti Elédùmarè rí sí wa.
Chorus:
Abiyamọ ayérayé ni Ẹlẹ́dàá wa.
Ẹnití Ó n tọ́ ọmọ-ọmú pẹ̀lú ìyáa rẹ̀.
Ó ń pèsè fún gbogbo ohun ẹlẹ́mìí.
Gbogbo wọn pátá ni Ó ń ràdọ̀bò.
Mímọ́, mímọ ni ti Olúwa Ọlọ́run ELÉDÙMARÈ
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ