- Poem For Fasting
Elédùmarè àwa kì yóò f’ẹnu ba oúnjẹ,
Bí kò ṣe pé O dáhùn àdúrà wa.
Èrè kíni ohun jíjẹ já sí,
Nígbà ọkàn wá bá ṣàárẹ̀?
Chorus:
Baba wa tí ń bẹ l’ọ̀run,
Dáhùn àdúrà wa.
A bá burú-burú níwájú Rẹ,
Nnú àwẹ̀ la wá bẹ̀bẹ̀.
Òórùn iyán ti dá nimú wa,
Òùngbẹ ọtí kò sí.
Wàhálà yí pọ̀ jù fún wa,
Ọkàn wá rẹ̀wẹ̀sì.
Chorus:
Baba wa tí ń bẹ l’ọ̀run,
Dáhùn àdúrà wa.
A bá burú-burú níwájú Rẹ,
Nnú àwẹ̀ la wá bẹ̀bẹ̀.
Ahọ́n wá wúwo fún ‘bànújẹ́,
Ojúu wá pọ́n roro.
Àwọn ògo-wẹrẹ pàápàá,
Kò ṣiré lóríi pápá.
Chorus:
Baba wa tí ń bẹ l’ọ̀run,
Dáhùn àdúrà wa.
A bá burú-burú níwájú Rẹ,
Nnú àwẹ̀ la wá bẹ̀bẹ̀.
Elédùmarè bojúwolẹ̀,
Kí o dáhùn àdúrà wa.
Baba jọ̀wọ́ má kọ̀ wá sílẹ̀,
Nígbà a ké pè Ọ̀.
Chorus:
Baba wa tí ń bẹ l’ọ̀run,
Dáhùn àdúrà wa.
A bá burú-burú níwájú Rẹ,
Nnú àwẹ̀ la wá bẹ̀bẹ̀.
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ