- Poem For Children
Abiyamọ gbogbo àgbáyé,
Àwọn ọmọ-wẹẹrẹ wá d’ọwọ́ Rẹ.
Kọ́ wa láti tọ́ wọn lọ́nà òtítọ́,
Nitori ìwọ l’Ọlọ́run òdodo.
Chorus:
Elédùmarè, pa àwọn ọmọ wa mọ́.
Kọ́ wọn ní ọ̀nà òdodo Rẹ.
Máṣe gbà fún àṣá ayé láti gbé wọn lọ.
Fi ìfẹ́ gbá wọn mọ́ àyà Rẹ.
Ìkọsẹ̀-j’ayé wọn ń bẹ lọ́wọ́ Rẹ,
Elédùmarè dákun máa tó wọn.
Máṣe jẹ́ kí wọn kọ ìlànà ìṣẹ̀ṣe Rẹ.
Nínú àánú ni kí O máa tọ́ wọn.
Chorus:
Elédùmarè, pa àwọn ọmọ wa mọ́.
Kọ́ wọn ní ọ̀nà òdodo Rẹ.
Máṣe gbà fún àṣá ayé láti gbé wọn lọ.
Fi ìfẹ́ gbá wọn mọ́ àyà Rẹ.
Ojú mẹ́rin ló ń bí ọmọ,
Igba ojú nií wòó.
Èdùmàrè, a ti bí wọn,
Ṣùgbọ́n ìwọ lo le wò wọn.
Chorus:
Elédùmarè, pa àwọn ọmọ wa mọ́.
Kọ́ wọn ní ọ̀nà òdodo Rẹ.
Máṣe gbà fún àṣá ayé láti gbé wọn lọ.
Fi ìfẹ́ gbá wọn mọ́ àyà Rẹ.
Gba àwọn ọmọ wọ̀nyí,
Lọ́wọ́ ayé àti ọ̀làjùu rẹ.
Èdùmàrè máa jẹ́ kí wọ́n ṣá Ọ tì,
Má jẹ́ kí wọ́n ṣáko lọ.
Chorus:
Elédùmarè, pa àwọn ọmọ wa mọ́.
Kọ́ wọn ní ọ̀nà òdodo Rẹ.
Máṣe gbà fún àṣá ayé láti gbé wọn lọ.
Fi ìfẹ́ gbá wọn mọ́ àyà Rẹ.
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ