(16). Poem for children (Omo)
Bí ofà ti rí lówó alágbára
Béèni àwon omo ìgbà èwe re
Àwon omo ni ìní olúwa
Omo inú sì li ère rè
Elédùmarè osé tóo fún mi l’ómo bí
Elédùmarè tó mo iyì omo
Elédùmarè dá àbò re bo àwon omo mi
Èmi yóò tó omo mi ní ònà tí yíó tò,
nígbàtí ó bá sì dàgbà tán,
kì yíò kúrò nínú rè
Omo mìi, gbó èkó mìi,
kí ìwo kí ó má sì ko ohùn ìyá re sílè.
Elédùmarè osé tóo fún mi l’ómo bí
Elédùmarè tó mo iyì omo
Elédùmarè dá àbò re bo àwon omo mi
Omo omo ni adé arúgbó
Ògo won sì ni bàbá won
Èmi kò ní mú àwon omo mìi bínú
Sùgbón màá tó won nínú èkó àti ìkìlò
Elédùmarè osé tóo fún mi l’ómo bí
Elédùmarè tó mo iyì omo
Elédùmarè dá àbò re bo àwon omo mi
Èmi yíò kó àwon omo mìi ní òfin Elédùmarè
Àlááfíà àwon omo mìi yíó sì pò
Omo mìi e má gbó ohun tí mo bá yín wí.
Elédùmarè osé tóo fún mi l’ómo bí
Elédùmarè tó mo iyì omo
Elédùmarè dá àbò re bo àwon omo mi
Mimo Mimo ni ti Oluwa olorun ELEDUMARE
Iba fun ELEDUMARE
Iba Asee