Poem For Diversity
Elédùmarè l’áwa ìran Odùduwà n pèé!
Chukwu l’àwọn ẹ̀yà Ìgbò n yìn Ọ́!
Raka-dende l’àwọn Lárúbáwá n rọ̀dẹ̀dẹ̀ yí ìtẹ́ ògo Rẹ ká.
Ìwọ Ọba ayérayé, Ọba tí ó ba lórí ohun gbogbo.
Chorus:
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo dá wa.
Ní ìran-ìran lo dá gbogbo wa.
Ohun-ọ̀gbìn ní irúú tiwọn.
Èdè awọn orílẹ̀-èdè ni ẹ̀dà tiwọn.
Ìwọ lo dá àfín.
Ìwọ lo dá òyìnbó tí ó fẹ́ fi ara jọ àfín.
Ìwọ lo dá àwa aláwọ̀-dúdú.
Ìwọ kan náà lo dá àwọn aláwọ̀-ṣe-Júù.
Chorus:
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo dá wa.
Ní ìran-ìran lo dá gbogbo wa.
Ohun-ọ̀gbìn ní irúú tiwọn.
Èdè awọn orílẹ̀-èdè ni ẹ̀dà tiwọn.
Okòólénígba èdè la fi n yìn Ọ́ l’ágbàálá ayé.
Mímọ́, mímọ, mímọ ni gbogbo wa ń wi.
Alelúyà fún Ọba aṣẹ̀dá gbogbo àgbáyé
Sí Elédùmarè ni a kan sáárá si.
Chorus:
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo dá wa.
Ní ìran-ìran lo dá gbogbo wa.
Ohun-ọ̀gbìn ní irúú tiwọn.
Èdè awọn orílẹ̀-èdè ni ẹ̀dà tiwọn.
Gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ l’on rọ̀dẹ̀dẹ̀ yí ògo Rẹ ká.
Ní ìra-ìra lo dá wọn.
Ọ̀run kanáà lo ta sóríi gbogbo orílẹ̀-èdè.
Òòrùn kanáà, àti òṣùpá kanáà.
Chorus:
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo dá wa.
Ní ìran-ìran lo dá gbogbo wa.
Ohun-ọ̀gbìn ní irúú tiwọn.
Èdè awọn orílẹ̀-èdè ni ẹ̀dà tiwọn.
Mímọ́, Mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run ELÉDÙMARÈ
Ìbà fún ELÉDÙMARÈ
Ìbà Àṣẹẹ!