Poem on Peace Making
Gbogbo orílè-èdè ń gbógun ti ara wọn.
Ìran èkíní sí èkejì.
Àwọn ẹ̀yà ń gbógun ti ara wọn.
Wọ́n ń dáná sún àwọn ìlú olódi.
Àwọn ìran kanáà nígbà ilé-ìṣọ́ọ Bábélì,
Wọ́n ń ka ara wọn sí ẹ̀yà àjòjì.
Wọ́n n’kórira ara wọn.
Wọ́n n’ta ẹ̀jẹ̀ ara wọn.
Chorus:
Elédùmarè bójú wolẹ̀ nínú àánú Rẹ!
Ìbínú Rẹ yíò a ti pẹ́ tó lórí gbogbo ayé?
Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ-ọmú Rẹ!
A fọ́n ẹ̀jẹ̀ wọ́n káàkiri àgbáyé.
Ìpàyà wà nílè àti lóko.
Ọfà ń fò kiri lójú ọrùn.
Àdó-olóró ń dá èmi légbodò.
Ẹlẹ́dàá a ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọ.
Dìde kí Ó pàṣẹ ìdákẹ́jẹ́ sí gbogbo ìgbógun.
Mú kí gbogbo ayé p’òùngbẹ àlàáfíà.
Jẹ́ kí gbogbo wa tún wárìrì níwájú rẹ
Níbi tí a óò tí máa kọrin wípé;
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run ELÉDÙMARÈ
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Aṣẹẹ