*Poem on Peace Making( Alafia)*
Orílè-èdè ń dide Ogun
si ra won ni to ri agbara
eya gbógun ti ara wọn pelu.
Ìran èkíní sí èkejì.
Àwọn omo eniyan ń gbógun ti ara wọn.
Wọ́n ń dáná sún àwọn ìlú olódi.
chorus
Elédùmarè fun wa ni Alafia to ye ko ro
Elédùmarè fun wa ni irorun.
Elédùmarè fun Okan wa ni isimi
Àwọn ìran kanáà nígbà ilé-ìṣọ́ọ Bábélì,
Wọ́n ń ka ara wọn sí ẹ̀yà àjòjì.
Wọ́n n’kórira ara wọn.
Wọ́n n’ta ẹ̀jẹ̀ ara wọn.
chorus
Elédùmarè fun wa ni Alafia to ye ko ro
Elédùmarè fun wa ni irorun.
Elédùmarè fun Okan wa ni isimi
Elédùmarè bójú wolẹ̀ nínú àánú Rẹ!
Ìbínú Rẹ yíò a ti pẹ́ tó lórí gbogbo ayé?
Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ-ọmú Rẹ!
A fọ́n ẹ̀jẹ̀ wọ́n káàkiri àgbáyé.
chorus
Elédùmarè fun wa ni Alafia to ye ko ro
Elédùmarè fun wa ni irorun.
Elédùmarè fun Okan wa ni isimi
Ìpàyà wà nílè àti lóko.
Ọfà ń fò kiri lójú ọrùn.
Àdó-olóró ń dá èmi légbodò.
Ẹlẹ́dàá a ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọ.
chorus
Elédùmarè fun wa ni Alafia to ye ko ro
Elédùmarè fun wa ni irorun.
Elédùmarè fun Okan wa ni isimi
Dìde kí Ó pàṣẹ ìdákẹ́jẹ́ sí gbogbo ìgbógun.
Mú kí gbogbo ayé p’òùngbẹ àlàáfíà.
Jẹ́ kí gbogbo wa tún wárìrì níwájú rẹ
Níbi tí a óò tí máa kọrin wípé;
chorus
Elédùmarè fun wa ni Alafia to ye ko ro
Elédùmarè fun wa ni irorun.
Elédùmarè fun Okan wa ni isimi
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run ELÉDÙMARÈ
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Aṣẹẹ