- Poem For Birthday
Ìṣẹ́jú n di wákàtí,
Wákàtí n di ọjọ́,
Ọjọ́ n di ọ̀sẹ̀,
Ọ̀sẹ̀ n di oṣù,
Oṣù n di Ọdún.
Chorus:
Ẹlẹ́dàá wa a dúpẹ́ fún ore-ọ̀fẹ́ ayé wa,
Ìwọ nìkan lo lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ayé wa.
Ìyè n di oyún,
Oyún n di ọmọ,
Ọmọ n di ìkókó,
Ìkókó n di ọ̀dọ́,
Ọ̀dọ́ n di àgbà.
Chorus:
Ẹlẹ́dàá wa a dúpẹ́ fún ore-ọ̀fẹ́ ayé wa,
Ìwọ nìkan lo lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ayé wa.
A kọ́kọ́ lọ jẹ́léósinmi,
A tún wọ ilé-ẹ̀kọ́ alakọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀,
A di èrò ilé-ìwé kékeré,
A gòkè s’ilé-ìwé gíga,
Kí a tó fẹ̀yìntì ní Ifáfitì.
Chorus:
Ẹlẹ́dàá wa a dúpẹ́ fún ore-ọ̀fẹ́ ayé wa,
Ìwọ nìkan lo lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ayé wa.
A tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí àpọ́n,
Kẹ̀rẹ̀-kẹ̀rẹ̀ a d’òṣìṣẹ́,
Nígbòóyá a di l’ọ́kọ-l’áya,
Orí tún sọ́ wá di alábiyamọ,
Bẹ́ẹ̀ l’ọjọ́ ayée wa m’búṣe.
Chorus:
Ẹlẹ́dàá wa a dúpẹ́ fún ore-ọ̀fẹ́ ayé wa,
Ìwọ nìkan lo lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ayé wa.
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ