- Poem For Spirituality of Life
Jẹ́ kin súnmọ́ Ọ́ lọ́jọjọ́,
Ọlọ́run Elédùmarè.
Jẹ́ kin lè máa f’ọkàn tọ́ Ọ,
Nínú gbogbo ìṣe mi.
Chorus:
Kí gbogbo èrò mi,
Gbé Elédùmarè ga.
Kí n j’ólóòtítọ́ sí Ọ,
Àti sí gbogbo aráyé.
Jẹ́ kí n fi ìwà pẹ̀lẹ́ hàn,
Bíi omi tútù ti ń ṣàn.
Jẹ́ k’àwọn ènìyàn,
Rí títóbi Rẹ láyé mi.
Chorus:
Kí gbogbo èrò mi,
Gbé Elédùmarè ga.
Kí n j’ólóòtítọ́ sí Ọ,
Àti sí gbogbo aráyé.
Gẹ́gẹ́ bí oorun ti ń tàn ògo rẹ̀,
Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.
Elédùwà lò mi l’ójojúmọ́,
Fún ọlá orúkọ Rẹ.
Chorus:
Kí gbogbo èrò mi,
Gbé Elédùmarè ga.
Kí n j’ólóòtítọ́ sí Ọ,
Àti sí gbogbo aráyé.
Ọkàn mi ń p’òùngbẹ àti sìn Ọ,
Baba Ẹlẹ́dàá mi.
Dákun f’ọwọ́ tọ́ ayé mi,
Kí n lè sìn Ọ́ síi.
Chorus:
Kí gbogbo èrò mi,
Gbé Elédùmarè ga.
Kí n j’ólóòtítọ́ sí Ọ,
Àti sí gbogbo aráyé.
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ