Fathers 13

(Poem for father in yoruba)

 

Ife baba po lori omo,ise baba po lori kinni omo fe je, kinni omo fe mu,bawo lomo yo se je Eyan laye, baba ni foto omo,sura baba ni omo gbe waye,

 

Chorus: Bi oju ti je oba ara,beni awon baba je,awon ni bale ile, Eledumare,bukun fun emi re ati okan re,ki jigi mi mase wo mi.

 

Awokose omo ni baba je,oruko baba ni omo je, Yala okunrin tabi Obirin,baba ni angeli omo to n dabo bo omo.Abere ki kohun aso,omo o gbodo yehun baba re tori egun ni fun omo.

 

Chorus: Bi oju ti je oba ara, beni awon baba je, awon ni bale ile, Eledumare, bukun fun emi re ati okan re, ki jigi mi mase wo mi.

 

Baba ni aladura ti n wure alubarika fun omo,baba ni olubukun omo,oun na ni oludanwo,olujise ati alase lori omo.baba loto lati fa omo re Obirin fun oko, oun na loni ojuse a ti ran omo lo ile iwe abi ise kiko.

 

Chorus: Bi oju ti je oba ara, beni awon baba je, awon ni bale ile, Eledumare, bukun fun emi re ati okan re, ki jigi mi mase wo mi.

 

Baba ni olopa ile,soja odede, baba ni adajo ile.oun na ni agbofinro, baba ni awako ile ti n ko gbogbo ebi re sinu re,baba ni fijilante ti o gbodo sun,ti n so ile, ti baba ba rin irin ajo jinjin,bi o de kosi eni ma pase ni ile.

 

Chorus: Bi oju ti je oba ara, beni awon baba je, awon ni bale ile, Eledumare bukun fun emi re ati okan re, ki jigi mi mase wo mi.

 

Mimo Mimo Ni Oluwa Olorun Eledumare

Iba fun Eledumare

Iba Ase

Leave A Comment

Shopping Cart (0 items)

Subscribe to our newsletter

Sign up to receive latest news, updates, promotions, and special offers delivered directly to your inbox.
No, thanks