- Poem For Wakeup Time
Orin Òwúrọ̀
Nínú gbogbo ewu òkùnkùn,
Elédùmarè l’on ṣọ́ mi.
Nígbà mo tún jí s’ọ́jọ́ titun,
Èdùmàrè mo gbé ọ ga.
Chorus:
Fún ìmọ́lẹ̀ alààyè, a dúpẹ́,
Elédùmarè a tẹríba.
Olú-odù dá ààbò bo wá lónìí,
Fi ọwọ́ agbára Rẹ ṣọ́ wa;
Àwọn tó pamọ nìkan ṣoṣo,
L’o nbọ́ nínú ewu.
Chorus:
Fún ìmọ́lẹ̀ alààyè, a dúpẹ́,
Elédùmarè a tẹríba.
Nínú ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa,
Kí á má ṣẹ̀ sí Ọ.
Tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ènìyàn,
Yóò fi rí ògoò Rẹ láyé wa.
Chorus:
Fún ìmọ́lẹ̀ alààyè, a dúpẹ́,
Elédùmarè a tẹríba.
Jọ̀wọ́ má jẹ́ kí a kọ̀ Ọ́ sílẹ̀,
Gbòǹgbò ìṣẹ̀dáa wa.
Jẹ́ kí a lè máa sìn Ọ́,
Àní títí dé òpin.
Chorus:
Fún ìmọ́lẹ̀ alààyè, a dúpẹ́,
Elédùmarè a tẹríba.
Mímọ́ mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ