Education 16

  1. Poem For Education 

 

Olódùmarè àwa ọmọ rẹ dé, 

Láti wá kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Rẹ. 

Kọ́ wa láti mọ ìyàtọ̀ kádàrá, 

Àti àwọn ère àfọwọ́fà. 

Chorus:

Alákóso-ayé jọ̀wọ́ kọ́ wa, 

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, odù ayérayé. 

 

Kí ni ilé-ìwé gíga, 

Bí kò sí ìmọ̀ Elédùmarè nibẹ? 

Kí ni kókó ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 

Bí ìlànà ọ̀pẹ̀lẹ̀ bá pòórá? 

Chorus:

Alákóso-ayé jọ̀wọ́ kọ́ wa, 

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, odù ayérayé. 

 

Kọ́ wa ní ojú odù kọ̀ọ̀kan. 

Bí a tií túmọ̀ Èjí Ogbè de Òtúúrúpọ̀n. 

Kọ́ wa bí a tií wòye àwọn ìgbà. 

Kọ́ wa bí a tií woye àkókò. 

Chorus:

Alákóso-ayé jọ̀wọ́ kọ́ wa, 

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, odù ayérayé. 

 

Elédùmarè kọ́ wa ní ọ̀nà Rẹ, 

Kọ́ wa láti ìtẹ́ ọrùn wá. 

Kọ́ wa láti mú sùúrù,

Sì kọ́ wa ẹ̀wẹ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ọ Rẹ. 

Chorus:

Alákóso-ayé jọ̀wọ́ kọ́ wa, 

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, odù ayérayé. 

 

Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè 

Ìbà fún Elédùmarè 

Ìbà Àṣẹẹ

Leave A Comment

Shopping Cart (0 items)

Subscribe to our newsletter

Sign up to receive latest news, updates, promotions, and special offers delivered directly to your inbox.
No, thanks