- Poem For Feasting
Olùpèsè ìwọ l’ọpẹ́ yẹ,
Fún àsè mọ̀lẹ́bí yìí.
Ìwọ lo kó gbogbo wa jọ,
Láti wá jẹun kí a sì yọ̀.
Chorus:
Baba Ọlọ́wọ́-gbọgbọrọ,
Yà àsè yí sí mímọ́.
Pèsè fún àwọn tí kò rí jẹ́,
Túbọ̀ máa bọ́ àwa ọmọ Rẹ.
Má jẹ́ ká tàpá sí Ọ,
Bí a bá yo tán.
Má jẹ́ ká f’ojú di Ọ́,
Bí a bá mu tán.
Chorus:
Baba Ọlọ́wọ́-gbọgbọrọ,
Yà àsè yí sí mímọ́.
Pèsè fún àwọn tí kò rí jẹ́,
Túbọ̀ máa bọ́ àwa ọmọ Rẹ.
Pa wá mọ kúrò nínú àjẹkì,
Baba rere ọ̀run.
Rántí àwọn aláìní,
Kí o sì pèsè fún wọn.
Chorus:
Baba Ọlọ́wọ́-gbọgbọrọ,
Yà àsè yí sí mímọ́.
Pèsè fún àwọn tí kò rí jẹ́,
Túbọ̀ máa bọ́ àwa ọmọ Rẹ.
Jẹ́ kí oúnjẹ yí fún wa lókun,
Kí èso wonyi mú wa láradá.
Máṣe jẹ́ kí wọ́n gbòdì nínú wà,
Baba wa òníìfẹ́-jùlọ.
Chorus:
Baba Ọlọ́wọ́-gbọgbọrọ,
Yà àsè yí sí mímọ́.
Pèsè fún àwọn tí kò rí jẹ́,
Túbọ̀ máa bọ́ àwa ọmọ Rẹ.
Mímọ́, mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run Elédùmarè
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ