Poem on the Importance of Water
Omi!
Kìkì ládùúgbò tó kún fún omi ni gbogbo ayé.
Bẹ́ẹ̀ sì ni Elédùmarè wòye ohun tí yóò fi àgbáálá ayé ṣe.
Ló bá rán Ọ̀rúnmìlà láti fi ikarahun erùpẹ̀ òn adìyẹ tẹ́ omi ayé l’áṣọ,
Tí ó sì fi ìṣàn omi ṣe Ẹ̀rìnjẹ̀ṣà ní ọ̀ṣọ́.
Chorus:
Kí ni ilé ayé bí kò sí omi?
Kí ni ọmọ-ènìyàn bí kò sí ẹ̀mí?
Bí èmi Elédùmarè kò bá rábàbà lórí omi,
Báwo ni ènìyàn àti gbogbo ẹranko yóò ṣe mí?
Ọjọ́ tí Elédùmarè bínú wàyíí!
Háà! Omi náà ló tún fi pa ayé rẹ́.
Ó pàṣẹ fún Olókùn àti Ọ̀ṣun láti ṣí àwọn ọ̀gbun ayérayé.
O fi omi kún àwọn òkè ńláńlá ti Éfúráímù àti Séírì.
Chorus:
Kí ni ilé ayé bí kò sí omi?
Kí ni ọmọ-ènìyàn bí kò sí ẹ̀mí?
Bí èmi Elédùmarè kò bá rábàbà lórí omi,
Báwo ni ènìyàn àti gbogbo ẹranko yóò ṣe mí?
Ṣùgbọ́n Elédùmarè kìí bínú títí.
Nínú ìbínú Rẹ̀ ni ìyọ́nú tún dé.
Ó ní kí àwọn Ọmọlúwàbí ṣí fèrèsé ọkọ̀.
Níbẹ̀ ni Núà gbé rí odù òṣùmàrè.
Chorus:
Kí ni ilé ayé bí kò sí omi?
Kí ni ọmọ-ènìyàn bí kò sí ẹ̀mí?
Bí èmi Elédùmarè kò bá rábàbà lórí omi,
Báwo ni ènìyàn àti gbogbo ẹranko yóò ṣe mí?
Bẹ́ẹ̀ ni Núà tẹríba ní ìwárìrì.
Ó sì pe Ọlọ́run ní Elédùmarè.
Báyìí ni Elédùmarè bá àwa ọmọ ènìyàn dá májẹ̀mú pẹ̀lú èdìdì òṣùmàrè
Láti máṣe tún fi omi pa ayé rẹ́ mọ́.
Chorus:
Kí ni ilé ayé bí kò sí omi?
Kí ni ọmọ-ènìyàn bí kò sí ẹ̀mí?
Bí èmi Elédùmarè kò bá rábàbà lórí omi,
Báwo ni ènìyàn àti gbogbo ẹranko yóò ṣe mí?
Mímọ́, Mímọ́ ni ti Olúwa Ọlọ́run ELÉDÙMARÈ
Ìbà fún Elédùmarè
Ìbà Àṣẹẹ!